By Ogunwoye Samson Gbemiga and Translated to Yoruba language by Aiyelabegan Akinkunmi Baba Awo...
Fún bí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn,Mo kórìíra gbèsè àti Ọ̀yá púpọ̀,kódà mo ti fìgbàkan ṣe ààlọ̀/ìwàásù lórí ìlòdì sí àti gbèsè jíjẹ nítorí pé n ò rí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àbáyọ gidi,àmọ́ o, àwọn ìṣeése wa tí fi lè jẹ́ yíyá níwọ̀n ìgbà tí fìrífìrí kò ti jọ òkolonbo!
Ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ẹ̀yáwó gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àbáyọ gbòógì,gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n ọmọ ìlú/ìpínlẹ̀, àwọn ìdí pàtàkì méjì wá sími lọ́kàn lọ́gán, àkọ́kọ́ ni àwòmọ́/ìhùwàsí aṣaàjú tó fẹ́ yá owó àti kín ni a fi owó tí a fẹ́ yá náà sọrí gan an? Ṣé ìráà ni àbí ohun ìlọsíwájú?
Nínú ètò-ọrọ̀ ajé/Òṣèlú, o hàn kedere pé ẹ̀yáwó tàbí ọ̀yá méjì la ní, àwọn ni ;Ọ̀yá ìlọsíwájú àti Ọ̀yá ìfàsẹ́yìn.
Ìyàtọ̀ ọ̀yá/ẹ̀yáwó méjèèjì kò sàì fojú hàn kedere. Ọ̀yá ìlọsíwájú ni à ń lò fún àwọn ètò tí yó mú ayé rọ mẹ̀kúnnù lọ́rùn gbẹdẹmukẹ tí yó sì tètè mú àbájáde wá lọ́gán, ṣùgbọ́n ọ̀yá abánikọ́wọ̀ọ́rìn ni ti èkejì tó kún fún àsepámọ́ aìláṣeyọrí,kódà àwọn onímọ̀ tí neo-liberal tún kan sáárá sí ìgbésẹ̀ ọ̀yá/ẹ̀yáwọ onílọsíwájú.
Wípé Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́,Abíọ́lá Ajímọ́bi rú gbèsè ìpínlẹ̀ yìí sókè ní ìlọ́po lọ́nà ọgọ́fà(120%) láì rí àṣeyọrí kan gbòógì tọ́kasí jẹ́ ohun tó yẹ kó ṣe ọlọgbọ́n ní kàyééfì, ọdún mẹ́jo lórí àlééfà pẹ̀lú òbítíbitì gbèsè láìsí ohun ìtọ́kasí gúnmọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀yá/ẹ̀yáwó onífàsẹ́yìn gidi. Àwọn ẹ̀yáwó ìjọba Ajímọ̀bi ni wọ́n lò fún àwọn iṣẹ́ àkànṣe tí wọ́n gbé owó gọbọi gùn lórí ju iye tí wọ́n ṣe é lọ, ní èyí tí àwọn iṣẹ́ àkànṣe náà kò sì padà rí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́.
Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ tí à ń sọ wọ̀nyìí, àwọn alágbàṣe tòǹbòlò/àìmọ̀rí ni wọ́n gbé iṣẹ́ fún, tí ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù sì ń rá. Bílíọ̀nù méje owó náírà tí wọ́n gbé jáde fún àwọn agbasẹ́se tòǹbòlò/àìmọ̀rí lórí iṣẹ́ àkànṣe òpópónà Ìbàdàn-Mọ́níyà-Ìṣẹ́yìn jẹ́ àpẹẹrẹ àìse déédé,ìnákúnàá ìjọba àná tí à ń sọ yìí. Adeniyi Olowofẹla, ọ̀kan lára àwọn alákòóso lábẹ́ Ajímọ̀bi sọ pé ìdá ogójì (40%) nínú owó ọ̀yá náà ni àwọn lò láti san owó àjẹmọ́nú àwọn òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì, ẹ ò rí irọ́ bàǹtà bí? Ọ̀fọ́n ọ̀n tó fa ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ yìí ṣẹ́yìn, tí kò sì bu ọlá kankan fún ètò ọrọ̀ ajé wa.
Ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ yìí náà kò sàì jẹ́ akópa nínú ètò agbomilójúẹni yìí. Ààrẹ Mohammadu Buhari náà rú gbèsè ilẹ̀ yìí sókè sí ìdá àádọ́fà(110%) láì lè rí àṣeyọrí gidi tọ́ka ẹ̀. Ìrètí mi ni pé ìjọba àpapọ̀ yó yá owó fún ìgbédìde ilé-iṣẹ́ Àjàòkúta Steel Mill, èyí tí yó ṣe ìrànwọ́ fún mímú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dìde kúrò nínú ọ̀kùnrùn ọrọ̀ ajé tó dá a gúnlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, Àjàòkúta Steel Mill kápá àti gba òṣìṣẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500,000)ká má sẹ̀sẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí yó ní ìwọ̀n nípasẹ̀ àwọn ẹ̀wọ̀n iye, ṣùgbọ́n ìjọba fojú bíńtín tàbí ká tilẹ̀ sọ pé wọn kọ ihà kòkanmí sí abala náà.
Nígbà tí mo gbọ́ pé Gomina Ṣèyí Mákindé béèrè fún ìbuwọlù/ìyọ̀ǹda ẹ̀yáwó láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣòfin,mo kangìdì látí má kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ, nítorí pé mò ń retí ohun tí wọ́n fẹ́ fi owó náà ṣe. Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé n ò bá ìjákulẹ̀ pàdé rárá?ẹ̀yáwó náà wà fún àwọn iṣẹ́ àkànṣe tí yó mú ìrọ̀rùn bá ọ̀pọ̀ ènìyàn, tí yó sì ṣe kọríyá fún ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ yìí. Òtítọ́ míràn tó mú ẹ̀yáwó yìí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ni pé ó wá láti ilé ìfowópamọ́ olókoòwò abẹ́lé, kìí ṣe ẹ̀yáwó ti ilẹ̀ òkèèrè rárá.
Níwọ̀n ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn, Gómìnà Ṣèyí Mákindé ṣe àbẹ̀wò sí Àkùfọ̀ Farm Settlement,ó sì ṣe ìlérí láti ṣe ìgbéga rẹ sí ilé-isẹ́ ọ̀gbìn ńlá, látarí ìmọ̀ kíkún lórí ipa tí iṣẹ́ ọ̀gbìn kó nínú ìdàgbàsókè ìjọba ìwọ̀-oòrùn ọjọ́un, kò sí àní àní,ọlọgbọ́n ènìyàn ní láti fọwọ́sí irúfẹ́ ìgbésẹ̀ yìí, díẹ̀ lára owó ọ̀yá yìí ni yó jẹ lílò fún abala yìí, eléyìí yó jẹ kí ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ dá dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ nípa ìpèsè oúnjẹ, tí yó sì jẹ́ olùpèsè fún ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn ìpínlẹ̀ alámùúlétì rẹ̀. Ká má gbàgbé pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ni yó tún di oníṣẹ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú ètò yìí.
Bákan náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ àkànṣe ojúlówó tí yó jẹ́ tí ọrọ̀ ajé ńlá fún àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ yìí ni ètò ẹ̀yáwó yìí ti ṣe lọ́bẹ̀ sí kòkò, àwọn iṣẹ́ àkànṣe àsepatì bí òpópónà Ìbàdàn-Mọ́níyà-Ìṣẹ́yìn pẹ̀lú ìyípadà òpópónà Ìwó jẹ́ pàtàkì sí ìlọsíwájú ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.
Láti ṣe àfikún iṣẹ́ rere ọlọ́lá jùlọ, màá sín ìjọba ní gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́ pé kí wọ́n jí gìrì sí ètò ìrìn àjò afẹ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ China ń fojoojúmọ́ gbèrú sí i nítorí ìpayọ àwọn ohun ètò ọrọ̀ ajé wọn tí wọn kò dá gàgà lórí ọ̀kan ṣoṣo. Ní ọdún 2018 nìkan, abala ìrìn àjò afẹ́ nìkan pa ìdá méjìlá (12%) wọlé nínú àpapọ̀ owó tí orile-ede China pa wọlé lọ́dún náà.
Ìrìn àjò afẹ́ ti di atukọ̀ gidi fún ètò ọrọ̀ ajé, èèyàn tó sì lé ní ogún mílíọ̀nù ló ti di oníṣẹ́ lọwọ nípasẹ̀ ètò ìrìnàjò afẹ́. Bẹ̀rẹ̀ láti orí ògiri Ọlọ́lá ti ilẹ̀ China (Great Wall Of China) dé orí òpópónà Sílíkì (Silk road) àti àwọn ààyè ìtàn àkọọ́lẹ̀ míràn ti kó ipa takuntakun sí ìlọsíwájú ọrọ̀ ajé ilẹ̀ wọn.
Ọ̀yọ́-ile ní ìtàn ọlọ́lá tí ó labú etí òkun ilẹ̀ adúláwọ̀ já,kódà àwọn òyìnbó amúnisìn kò sàì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ohun àrà-kenge tó wà ní Òyọ́-ilé yìí.
Kódà ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àjèjì tó tó mílíọ̀nù ni wọ́n ń ṣèǹmọ̀,dígì,tí wọ́n sì ń dá itọ́ mì lórí àwọn ohun ìyanu mérììrí tó sodo sara àwọn akọni wa gbogbo ìgbà-n-nì, síse àgbéǹde ààyè ìgbafẹ́ ìjọba àpapọ̀ ti Ọ̀yọ́-ilé àti sísọ ọ́ di ibi fàájì yó mú ọlá òun iyì bá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sí i. Àtúntò àti àtúnṣe ló nílò, ibi ìgbafẹ́ àpapọ̀ ti Ọ̀yọ́-ilé kápá àti ṣe àfikún owó tó ń wọlé fún ìpínlẹ̀ yìí tí ìjọba bá jí gìrì sí i. Mo lérò pé lọ́jọ́ kan, Ìjọba kò ní sàì ṣe àbójútó tó péye sí èyí.
Ayélabégàn Akínkúnmi Baba Awo ló sògbufọ̀!
Comments
Post a Comment